Imole

Sola Allyson

Added on : Mar 17, 2021

Imole – Sola Allyson
Mar 17, 2021 Abimbola Tolulope
In Lyrics

Jesu
Imole
Ategun ati afara sibi imole
Jesu
Enit’O wa
Ife e Baba
S’eni t’o fe d’omo

Repeat

Imole, lat’inu imole
O wa lati da wa pada s’ona imole
Ooun t’o gb’aye
Ko je k’on mo imole
Won di’te moo ife e baba
Olorun ninu eniyan
Eniyan ninu Olorun
Ilekun awon aguntan sinu ile aanu
Ipase eniti mo gba igbala
N’aye tii fi funni ko
Imole s’ookun aye e mi
Olusewosan emi i mi

Jesu
Imole
Ategun ati afara sibi imole
Jesu
Enit’O wa
Ife e Baba
S’eni t’o fe d’omo

Eni nwa imole
Won ri ii imole
Won o mo mole
Won di’te imole
Irora yen po gan
Eje at’omi nsan gan
Sibe o n s’agbawi fun wa
Pe baba dariji won
Won o mo’ohun a nse
Baba dariji wa o nitori imole
Ninu irora re o tun fi iyonu mu ole re para
O ni iya wo omo re, omo wo iya re
O kigbe l’ohun rara
Olorun mieese t’o o ko mii le
Eese t’o o ju mii le
Eese t’o o yin mi nu
Ongbe po gan, oti kikan l’aye fun un
Awon t’o nwa imole o, won f’iya je imole
O ba pari, o pari
Imole f’emi e s’owo o baba
O pari!

Nitori imole, nitori imole
Aso ipele ya o
Nitori imole
A le pe baba ni baba nitori imole
Isa oku d’ofo
Eni ba fe le wa d’omo

Jesu, oga ogo, olori ogun orun
Omo alade alaafia
Alase orun, aye e baba
Baba l’aaye o, Baba l’aye
Aye e mi tire ni
Tn imole nipase mi
Ogo o mi k’o fogo fun o
Ola a mi k’o bu ola fun o

Jesu, iwo ni imole
Ategun ati afara sibi imole
Jesu enit’owa
Mo ju’ba re, enit’oso mi d’omo

HOW HAS THIS IMPACTED YOUR LIFE?

Thank you for sharing. Show us some love by joining our community.

Send this to a friend