Call: Eni ba mo’nu ro, lo le mo ope da
Eni ba ni arojinle a saa ma dupe
Emi mo’nu ro, mo ya wa dupe
Olorun ti a ko le da duro, mo gbe oga o
All: Olorun ti a ko le da duro, mo gbe oga o(2x)
Call:Olorun ti a ko le mu lowo dani
Mo gbe o ga o
Too ba loya ta lole da o duro
Eto inu re lo wa, eto owo re lowa
Mo gbe o ga
All: Olorun ti a ko le da duro, mo gbe oga o(2x)
Call: Kabiyesi, kabiyesi re baba agba
Kabiyesi, kabiyesi re, oba awon oba
All: Kabiyesi, kabiyesi re baba agba
Kabiyesi, kabiyesi re, oba awon oba
Call: Kabiyesi re o, baba agba
Oba to joko lori ite o, maa sola re lo Oluwa
All: Kabiyesi, kabiyesi re baba agba
Kabiyesi, kabiyesi re, oba awon oba
Call:O fi imole s’aso bora
Oba to f’imole s’aso bora
Ori obiri aye lo joko si,
imole lo fi s’aso bora
Oba to f’imole s’aso bora
All: O f’imole s’aso bora (4x)
Call: Kabiyesi re Oluwa
Emi mi n bu ola fun o nigba gbogbo oba mi
Ni gbogbo aye ko seni to dabi re, Oluwa
Iwo to n joko sinu awon orun, Oluwa
All: O f’imole s’aso bora (4x)
Call: Oluwa mo gbe o ga (2x)
Awon orun n ba mi yin o o pe o se (2x)
All: Oluwa mo gbe o ga (2x)
Awon orun n ba mi yin o o pe o se (2x)
Call: Oluwa mo gbe o ga (2x)
Gbogbo ise re n ba mi yin o o pe o se
Mo da ohun mi po mo gbogbo ise re,
Mo so bee o seun
All: Oluwa mo gbe o ga (2x)
Awon orun n ba mi yin o o pe o se (2x)
Call: Ayin o oba mimo
A yin o oloore wa
A yin o, olugbala
Iwo lo n s’agbara wa
All: Ayin o oba mimo
A yin o oloore wa
A yin o, olugbala
Iwo lo n s’agbara wa
Call: Ayin o oba mimo
Ebo ope wa ree o
Lat’ogbun okan wa wa ni
Wa gba a Oluwa Olorun
All: Ayin o oba mimo
A yin o oloore wa
A yin o, olugbala
Iwo lo n s’agbara wa
Call: Iwo ni mo wa gbe ga
Iwo ni mo wa f’iyin fun
Olorun mi to n gbe nibi giga
Iwo ni mo wa gbe ga
All:Iwo ni mo wa gbe ga
Iwo ni mo wa f’iyin fun
Olorun mi to n gbe nibi giga
Iwo ni mo wa gbe ga
Call: Iwo ni mo wa gbe ga o
Oba to r’ojo aanu s’ori iseda mi, Oluwa
Olorun mi to n gbe nibi giga
Iwo ni mo wa gbe ga
All: Iwo ni mo wa gbe ga
Iwo ni mo wa f’iyin fun
Olorun mi to n gbe nibi giga
Iwo ni mo wa gbe ga
Call: Alpha, Omega(2x)
Iwo ni mo f’iyin fun o, baba(2x)
All: Alpha, Omega(2x)
Call: Iwo ni mo f’iyin fun o, baba(2x)
Oba to mo ibere, iwo ni Alpha,
Oba to mo opin, iwo ni Omega
Iwo ni mo f’iyin fun o, baba
Iyin re o ni tan lenu mi titi aye mi, Oluwa
All: Alpha, Omega(2x)
Iwo ni mo f’iyin fun o, baba(2x)
Call: Oloore ofe, eleruniyin
Olorun agbaye o, mo gbe o ga
All: Oloore ofe, eleruniyin
Olorun agbaye o, mo gbe o ga
Call: Oloore ofe, eleruniyin
Unexplainable, indescribable
Unsearchable, incredible
Mo gbe o ga
All: Oloore ofe, eleruniyin
Olorun agbaye o, mo gbe o ga
Call: Iyin ye Olorun wa, Oba to n gbo adura(2x)
All: Iyin ye Olorun wa, Oba to n gbo adura (2x)
Call: Iyin ye o o, Olorun wa
Oba to n fi aanu gbadua
Bi o ba se ‘wo too wa leyin mi, nibo lemi o ba wa
Mi i ba ti b’aye lo
Oba to n gba adura
All: Iyin ye Olorun wa, oba to n gbo adura(2x)
Call: O ti n s’ise re bo, iwo yoo se lasepe o
O ti n s’ise re bo, iwo yoo se lasepe
All: O ti n s’ise re bo, iwo yoo se lasepe
O ti n s’ise re bo laye wa, iwo yoo se lasepe
Call: O ti n f’aanu gba mi bo Oluwa
Iwo yoo gba mi tan o, agbanilagbatan ni o o
O ti n f’aanu gba mi bo Oluwa
Iwo yoo gba mi tan o, Agbanilagbatan ni o o
O ti n f’aanu yo mi bo o, oba to mu mi de’bi
Iwo yo se lasepe
All: O ti n s’ise re bo, iwo yoo se lasepe
O ti n s’ise re bo laye wa, iwo yoo se lasepe
Call: Gb’adura mi goke, baba, gb’adura mi goke
All: Oba afesejin (3x)
Gb’adura mi goke
Scripture says He watches over His word to perform it If He said it I believe it What He says,…
God is in our midst Right here right now Filling us with grace And more of Him God is in…
I could sing a song of love to Yahweh Yahweh, Yahweh, Yahweh Yahweh, Yahweh, Yahweh Oh how You love me…
I have tasted of Your mercy And I have come to realize There is nothing like it When You decide…
Oh oh oh oh oh Oh oh oh oh Oh oh oh oh oh Oh oh oh oh Hey brother…
A thousand years like a day gone by That I may dwell, here in Your arms To gaze on beauty…
Leave a Comment