Oruko Tuntun

Tope Alabi

Added on : Jul 20, 2020

Oruko Tuntun – Tope Alabi
Jul 20, 2020 Abimbola Tolulope
In Lyrics

Chorus (2x)
Olorun to da mi w’aye o,
Lo ni oruko mi amutorunwa
Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko
Emi lologo alayanmo ire
Mo w’aye wa f’ogo Olorun han
Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan

Solo 1:
Eto Olorun ni emi je
Aseda f’inu f’edo f’ife da mi
O mo mi ni iri Ohun gangan
Mi o ku si’bi kan, O da mi daradara
Emi lamo t’owo adaniwaye mo
Eemi aseda ni iwalaaye mi
Oju ogo re ni iriiran mi akoko
Ipa lo fi se mi s’inu iya mi
Ara nla owo oga ogo ni mi
Emi leniyan

Chorus

Solo 2:
Irin ajo eda wa s’aye, esu, ota, elenini eniyan n duro
Ami ibi to tele eda bo ni satani t’a le sokale lat’orun
O n bu ramuramu, o n kanra, lo fi n fi’bi han eda leemo
Eni ba w’aye (w’aye)
Eeyan to n gb’aye (gb’aye)
E maa sai bikita p’aye kun fun ibi

Chorus
Instrumentals…

Solo 3:
Ti Oluwa ni ile, ati ekun re
Ohun gbogbo to da s’oke eepe lo dara
Satani lo so won d’ibi
Eniyan e maa se ran lowo
Ma je ko f’ibi so e loruko
Ire ni’wo je o ma gbagbe
Oruko a maa ro ni
Jowo ma se bi alaigbon
Ohun t’aa ba n je la o da
Ara e gb’oruko t’awon eeyan n pe ‘ra won
(oruko t’on n pe ‘ra won)
E gb’oruko t’eniyan n pe ‘ra re (e gb’oruko t’on n pe ‘ra won)
Oloriburuku, talaka ni won n pe ‘ra won (oruko t’on n pe ‘ra won)
Agan, were, alarun ni won n pe ‘ra won (oruko t’on n pe ‘ra won)
Omugo, didndinrin ni won n pe ‘ra won (oruko t’on n pe ‘ra won)
Alayebaje, atoole n won n pe ‘ra won (e gb’oruko t’on n pe ‘ra won)
Aletilapa ni won pe omo won (oruko t’on n pe ‘ra won)
Ah e o mo p’ohun t’a ba pe loruko o lagbara lori eda

Instrumentals…

Solo 4:
Ohun ti o n la koja ooo,
Jowo ma fi pe’ra e mo
Enikeni to ni’dojuko isese kan
E ma fi pe loruko
Ma f’epe san epe, maa ko oruko buburu
Satani lo n je baun
A ti d’ele aye na,dandan ni k’a laagun
K’a to yo, sise pelu ero ire, wa a yo

Instrumentals…

Solo 5:
Awon elomiran a ni nile awon bi won o logun
Odun ni’gbeyawo won o ni le bimo
Won a ni nile won (won kii le ko’le)
Won a ni nile awon (won kii gbo k’on to ku)
Idojuko won (n’on fi n pe ‘ra won)
A ni aisan to n se ohun (n lo pa ‘ya ohun)
Won a tun fun loruko (alaarun idile)
Won a lohun gangan (logun ebi won)
Eda n f’oruko isoro (p’oriki ara re)
Won a ni b’o ti n se won (n’ile awon niyen)
Eda e so’ro to dara jade,ero alaafia l’Olorun ni si wa
Ma f’ogun enu se’ra e pa
Pe’ra e ni hun to fe je

Bridge:
Oruko to dara l’Olorun so mi
Oruko to logo o l’Eleda n pe mi
Oruko to dara ni emi n je
Aseda mo mi ire
Emi ako’rewaye
Emi agb’ayesayo
Mi o ya’gan lona kankan
Aisiki ola, wura oro,
Ara owo Aseda, lemi eniyan

Solo 6:
Igbagbo n se pupo loro eda (alaisan ti o ni’gbagbo ko le gba ‘wosan)
Ireti logun f’oruko tuntun (alainireti ko le kuro loju kan)
Eda segun nipa oro enu e (iku ati iye wa lori ahon)
Ma s’ahon d’ida fi sa ara e si wewe (wa a jere ohun to ba f’enu so)
Eni to da’ana s’aaro ti o gbe ‘hun le’na (o daju ko ni ‘hun se)
O kan fe ya’na lasan ni, igbagbo ni yo ba ero e sise
Ja ijangbara fun oruko rere, oruko lo n ro ni

Bridge

Solo 7:
Eda to n gbe inu aye
Yara pada sodo aseda
Ohun lo mo idi oro
Ohun lo le yanju e
F’adaniwaye se’didi aye re
Mura lati se atunse gbogbo
Ko lati je oruko t’aye n so ni
To ba yanmo ijakadi
Ore b’Olorun dowo po o
Ki aye e ko le to
Ore b’Olorun laja ko le j’oruko tuntun

Bridge

Solo 8:
Obedi-Edomu j’oruko tuntun (o j’oruko tuntun)
Bartholomew j’oruko tuntun (o je oruko tuntun)
Jakobu j’oruko tuntun (o j’oruko tuntun)
Dafidi j’oruko tuntun (o j’oruko tuntun)
Maria Magdaleni j’oruko tuntun (o j’oruko tuntun)
Soolu j’oruko tuntun (o je oruko tuntun)
Peteru apeja j’oruko tuntun oo (o j’oruko tuntun)
At’emi nipa eje odo aguntan
Mo gba ire, to je ini mi pada

Bridge
Instrumentals…

Solo 9:
Emi t’ada (Emi t’a da)
Laworan Olorun (Olorun)
Emi eda (Emi eda)
Mo ri ojurere (ojurere)
Mo loore ofe to ga julo
Emi lori (emi lori)
Mi kii se iru o (lailai)
Emi t’ada (Emi t’ada)
T’ewa t’ogo Olorun (Olorun)
Lat’odo Aseda o, ola mi o lakawe
A ti fi oruko tuntun pe mi, emi
A ti fi oruko tuntun pe mi, amin
A ti fi oruko tuntun pe mi, emi
A ti fi oruko tuntun pe mi, amin

HOW HAS THIS IMPACTED YOUR LIFE?

Thank you for sharing. Show us some love by joining our community.

Send this to a friend